Kí o tó fi plugin rẹ sílẹ̀, a rọ̀ ọ́ láti ṣe àgbéyẹ̀wò Àwọn Ìlànà wa kí o sì ka Àwọn Ìbéèrè Tí Wọ́n Máa Ń Béèrè Léraléra. Àkójọpọ̀ kúkúrú ti àwọn ìbéèrè tó wọ́pọ̀ wà ní ìsàlẹ̀ fọ́ọ̀mù náà.
Kí o tó lè gbé plugin tuntun sí ayélujára, jọ̀wọ́ wọlé.
Lẹ́yìn tí a bá ti fi sílẹ̀, a ó ṣe àgbéyẹ̀wò plugin rẹ pẹ̀lú ọwọ́ fún àwọn àṣìṣe tó wọ́pọ̀, àti láti ríi dájú pé ó bá gbogbo àwọn ìlànà mu.
Àwọn Ìbéèrè Tí Wọ́n Máa Ń Béèrè Léraléra
Báwo ni ìgbésẹ̀ àgbéyẹ̀wò yóò ṣe pẹ́ tó?
Èyí wà nínú FAQ Olùgbéejáde. Ó máa ń gbà laarin ọjọ́ 1 sí 10. A máa ń gbìyànjú láti ṣe àgbéyẹ̀wò gbogbo àwọn plugin láàrin ọjọ́ iṣẹ́ 5 lẹ́yìn ìgbéwọlẹ̀, ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ náà máa ń pẹ́ tó bá ṣe pẹ́ tó, ní ìbámu pẹ̀lú bí plugin rẹ ṣe díjú tó.
Báwo ni mo ṣe lè yára ṣe àgbéyẹ̀wò plugin mi?
A kò lè ṣe àgbéyẹ̀wò plugin rẹ ní àkọ́kọ́ ju àwọn mìíràn lọ, láti ràn wá lọ́wọ́ láti fọwọ́sí plugin rẹ ní kíákíá, jọ̀wọ́ ríi dájú pé o ti ka orí Àbò ti Ìwé Ìtọ́nisọ́nà Plugin.
Àwọn ìdí mẹ́ta wa tó wọ́pọ̀ jùlọ fún àìfọwọ́sí plugin ni:
- Plugin náà ní ìtújáde tí a kò yọ kúrò: Kọ́ nípa Yíyọ Dátà Kúrò
- Plugin náà gba dátà tí a kò sọ di mímọ́: Kọ́ nípa Sísọ Dátà Di Mímọ́
- Plugin náà n ṣiṣẹ́ lórí dátà fọ́ọ̀mù láìsí nonce: Kọ́ nípa Nonces
If the code in your plugin falls into one of the above categories, your plugin will not be approved. The Plugins Team will refer you back to these Handbook pages, adding further delay to the review process.
Kí ni URL plugin mi yóò jẹ́?
URL plugin rẹ yóò kún ní ìbámu pẹ̀lú ìníyelórí Orúkọ Plugin nínú fáìlì plugin àkọ́kọ́ rẹ (èyí tó ní àwọn àkọlé plugin). Tí o bá ṣètò tìrẹ bíi Orúkọ Plugin: Boaty McBoatface nígbà náà URL rẹ yóò jẹ́ https://wordpress.org/plugins/boaty-mcboatface slug rẹ yóò sì jẹ́ boaty-mcboatface fún àpẹẹrẹ. Tí plugin kan bá wà pẹ̀lú orúkọ rẹ tẹ́lẹ̀, nígbà náà ìwọ yóò jẹ́ boaty-mcboatface-2 àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó n hùwà gẹ́gẹ́ bíi àwọn orúkọ àkọsílẹ̀ WordPress.
Lẹ́yìn tí a bá ti fọwọ́sí plugin rẹ, a kò lè tún un sọ lórúkọ.
Mo ṣe àṣìṣe nínú orúkọ plugin mi. Ṣé kí n ṣe àtúnṣe rẹ̀?
Ó sinmi lórí ohun tí o fẹ́ yípadà. Tí o bá fẹ́ yí orúkọ àfihàn plugin padà, o lè ṣe àtúnṣe nípa ṣíṣe àtúnṣe àwọn fáìlì plugin rẹ ní ojú ìwé yìí. Tí ohun tí o fẹ́ yípadà bá jẹ́ ìjápọ̀ ayérayé / slug plugin rẹ, o lè ṣe bẹ́ẹ̀ LẸ́Ẹ̀KANṢOṢO kí á tó bẹ̀rẹ̀ àgbéyẹ̀wò (tí ó bá wà nílẹ̀, o ó rí ìjápọ̀ láti yí i padà ní ojú ìwé yìí). Tí èyí kò bá ṣeé ṣe, o ní láti kàn sí wa ní [email protected], a lè yí i padà níwọ̀n ìgbà tí a kò bá tíì fọwọ́sí plugin náà.
Kí ló dé tí n kò lè fi plugin sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn orúkọ àfihàn kan?
A ti fi òfin de àwọn orúkọ plugin kan nítorí ìlòkulò àmì ìṣòwò. Bákan náà, a ṣe ìdíwọ́ lílò wọn nínú àwọn slug plugin pátápátá fún ààbò rẹ.