Ebo
Ika Oturupon
Ika koo oturupon deere
Adifafun iba
Ti se omo oduduwa
Iba baba iba yeye
Iba oluwo iba ojugbona
Iba okute aroso ma gbaja
Ayamo fohun tawo ba dase
Koro ma saigba
Lo primero es que la persona pida y poner el ebo encima del tablero luego recitar Atepa Iwori
Atepa iwori awo erin
Adifafun erin
Erin sawo loke alo
Atagba atijokun
Toba ni kerin madalo
Tohun terin ni nlo
Eniyan toba ni kebo ma da
Ko maa bebo lo
Eso es para que el ebo sea aceptado
Ofun sai oya haa
Enikan kii fowo gbarun
Adifafun ajagbe
Ti n so gbogbo arun
Ti nara kaka alaile dide
Nje bewure ba bimo ti e
Oojo lomo re odide
Oferegege ajagbe dide oferegege
Baguntan ba bimo ti e
Oojo lomo re odide
Oferegege ajagbe adide oferegege
Badire okoko ba bimo ti e
Oojo lomo re odide
Oferegege ajagbe adide oferegege
Ko dide o eeru ogale ko dide
Despues quitar el ebo del tablero y poner las manos
Otun pele awo won lode aba
Adifafun won lode aba
Osi pele awo won lode abose
Adifafun won lode abose
Atowo otun atowo osi
Won kii sebo funmi aimoda
Yooyo ni tile oyo wa
Wuru wuru lo gbode owu lo
Apa ni tile alapa bo
Siwon lori asewele
Ebaa degun depe lawo lori o koleja
Asewele ode omode kunrin depenu
Despues se recitaran los adabo
Bi suku ba kangidi
Gbogbo ayaba ni gbowo ijo
Adifafun Adabo tise ojise olodumare
Niko awusi nile ifa, Adabo
Jowo jebo o da, Adabo
Nidoromu Awise nile IFA
Adabo, jowo jebo o da, Adabo
Niwonran Ola nibi ojumo ire ti mowa nile IFA, Adabo jowo debo oda, Adabo.
Eku tofin ni alara fi sebo
Eja tofin lalara fi sebo
Ikoro abenu haha lodo
Adifafun orunmila
Baba yoo gba alado ewila
Taya tomo oja o de
Awo agbala
Bi moba rawo rere a gbami la
Oturpon okanran
Ikin mi gaga nikin otolu aye
Akuko adie lohun iyere mafo
Awo otun nikosi agbe
Aragba lukeke difa awo ereja
Adifafun Ewi, Oto
Omo obayamu
Omo omi legbe legbe tii bawon yawe orisa
Ewe emi nifi n sebo ewe emi o jebo re ole mi
Ewe egbesi nifi n sebo, egbesi n si ebo re lona
Koko n gbebo rorun arebo
Koko n gbebo rorun arede
Ewe kan nbe loko
Ewe esuya, Esuya ki n raye jise Ebo.
Ose birete
Olele nidi ibon
Adifafun akinyagba
Ti somo elerupe
Nje ti aba fowo rubo komaafin
Ebo wa yoo maa da dorun ni
Akinyagba omo elerupe
Ebo wa yoo maa da dorun ni
Iya igba kii moowe ko moo mu
Komo re o gbe sinu eri
Adifafun tentere ope
Ti nlo ree gbe elebo leke
Niyo tiku ba nbo nko ifa
Tentere ope gbelebo leke
Nijo ti arun, ofo, egba gbogbo ajogun ibi
Ba nbo wa ifa
Tentere ope gbelebo leke tentere
Otua ka
Okin nigi nigi awo olokun
Adifafun olokun nijo ti omi
Olokun oto bu boju
Aluko dodo awo olosa
Adifafun olosa
Omi osa oto bu sin se
Odidere abinrin ese kerewe kerewe
Adifafun oluwo
Omo odo oba
Omo atorun la gbegba aje kari waye
Ifa ni otuka mo lo daka
Erigi lawo agbasa
Adifafun won ni sesin agere
Nijo ti won ji won wa ohun ebo kiri
Ifa a rohun ebo loni keeje
Kebo ofin erigi lawo agbasa
Ifa a rohun ebo
Despues recitar el odu que salio y ejiogbe-odi meji
Owonrin sogbe
Koko aso abeti sere sere
Adifafun yerepe ogele
Ti yoo gba ara re
Yoo si gbagi oko
Igi ti yerepe dimo
Igi ola loda
Keeru keeru kan ole ke
Agada godo gbaa
Adifafun alakisa
Ti n sebo ti o fesu je
Ebo esu ma loran
Eba je ka rubo fesu ko maa lo
Obara bogbe
Opon ide aboju telu
Adifafun Òrúnmìlà
Baba yoo bi tifase lomo
Tifase nigba yii o tifa se
Obara bgobe tifase
Ewure belewo won a seke peeru
Olugbongbo ti meekan wole
Adifafun iyami osoronga
Won n sawo rode ipokiya
Talo dawa losu afi n sawo
Iyami osoronga
Lo dawa losu afi n sawo
Ogunda bede
Enu won leji enu won leta
Adifafun alapinni iyofori
Omo abeegun jenu awo
Eele ranpin mi enu won
Eele ranpin mi lailai enu won
Kukute o mira jigi
Adifafun olankosin
Omo ajogun gbade bori
Ibi tawo ba soro si
Ikin mama je o ye
Awo rere ni kukute o mira jigi
Despues de estos versos decir
Bika ba kari ebo tan
Eji irete ni tee
Ika meji
Iwo lo rele ika
Iwo lo todo ika bo
Adifafun seere tii se obinrin sango
Ero opo ero ofa
Seere fidi bale omo ninkojo
Akerengbe ni opa guuru wamu
Adifafun odi abufun yara
Iwa odi nse iwa odi n baje
Gbogbo ware ware tin ekoko
Ekada ewa lo ree tunwa odi se
Ose birete
Abata nla ni baba efo wonyii
Adifafun ile
Ti n sukun pe oun o romo bi
Ebo lawo ni kose
O si gbegbo nibe orubo
Nje irinwo monle ebawa se
Igba imonle ebawa se ire
A sebi sile aja n roju
A o sebi sile aja n roju
Ipori aja o jobi ri
Iro ni won pa maja
Eni laja o fobi se
Adifafun agbagba looro
Ti se omo kunrin ode
Osun moriro koo ma dubule
Looro ganga laa bosun awo
Irete meji
Paafa teere ni ileke omi
Adifafun ire
Ti nlo ree te meji nifa
Ero opo ero ofa
Igba ire nte meji lara nro awo
Pete pete moju ona gba lo
Adifafun odo miragba
Ti nfomi oju sogbere omo
Omo toniwayu omo to leyin
Omo yooyo ni todo
Okanran oyeku
Yangi abori kugu
Adifafun olokanran
Ti omo re n yanku
Omo olokanran a e yanku mo o
Apari isuko kii joba
Okanran yeye
Adifafun won legun aweroro
Omo aleku gori odi lo
Awa leku gori odi lo nigbayii awa oku mo
Ati sebo okanran yeye
Ifa bawa leku gori odi lo
Ose iwori
Ose dudu mogbe eji o
Iwori pupa mogbe idoko
Adifafun lube abufun lube
Awon mejeji n sawo roko ode
Nje lube perin o
Lube si pefan
A o pawo rere lose iwori
Ose tura ooo
Gba tetetete
Ifa lose kukuru beni o kuru
Ose gigun beni o gun
Awon ajigbale owo moni sasara
Ojo patapata ni mule jekun
Osanso meji gba yigiyigi
Tete yagba kesan wo
Kio wo ise ti gbegi nse
Adifafun won nile ilose
Abufun won nile ojikan
Ola ojikan kole run
Owo koni tan
Nile ilose
Ola ojikan o le run
Too ni toluwo
Tufe ni tojugbona
Boyin koba seere
Etufu nigbe digi
Adifafun arugbo olufe
Ti n lo re bawon totufe gun
Won ni oni oso
Oni oun koni
Won ni oni aje
Oni oun koni
Won ni kilowa ni?
Oni afose lohun ni
Won ni tani owifun
Tio sefun ri
Oni oun sofun ila, ila sogun
Oun sofun ikan, ikan sogbon
Oun sofun oluyaya osadata
Nje gbohungbolo o de iyewa eko
Eyi awi gbogbo
Ni olorun gba
Gbogbo e ni ifa gbo
Gbogbo e logbalo
Ose awurela ifa ti gbo
Ope teere ifa iwo loba
Òrúnmìlà je n morimi lapo aye ja
Iyan bemubemu ninu odo
Oro bemubemu niku awon agba
Adifafun ami abufun ile
Nje ami oo
Oranmiyan
Awo debile gbe n gbire
Otun awo ode aba
Difafun won lode aba
Osi awo ode abosise
Difafun won lode abosise
Atotun, atotun kisebo fun ni kio moda
Mofi otun rubo
Ki tosi kio gba
Ise ti mo ba fi owo otun mi se
Ki n mo fi tosi danu
Mo san owo iku
Ki iku o ma pami
Mo san owo aru
Ki aru ki o mo se mi
Mo san owo ajogun gbogbo
Ki ajogun kio mo semi
Mo san owo alawi roko,
Alawi rodo, awon ki aroju eni kawire,
Awon ki apeyinda tan ki aso omiran,
Awon sorosoro fowo lu kijipa
Iyami o setan ti won o mo soro awotunde laida
Mosan owo won
Taye tie ni
Kehinde tie ni
Elegbe adagba
Oba o se ologun
Laba lase oluku tiran
Odu logbo o je
Esu aworo
Esu iba re
Orere iya lodo
Iya omo apo bi erupe ile
Eleko
Sare pegbe
Otun
Arin ago
Gbogbo won ni mo san owo won
Iyami osoronga apani mowagun
Eyin ni elewe
Eyin ni elegbo
Eyin lafefe
Eyin lefufu
Eyin lara iwaju
Eyin lero eeyin
Awo omokere ni mo se
Ki efi ti agbalagba gba
Ololo awo omi
Lodifafun omi
Omi torun bowaye
Ebo won ni kio se
Osi gbebo nibe orubo
Nje kaka komi o sina
Atari omi ko sai lana fomi rin
Okanran osa
Kamu ge nge lu ge nge
Awo ile ala koko
Igbin ni o lara ina yiya
Ihoho ni o gbadire gaja
Babalawo meta
Irukere mefa
Adifafun olu
Ti n sawo lo lu gbendu gbendu
Eyin won ran
Ogun ti won fi esin mu
Ti won mu
Eyi ti won fi oko ja
Ti won o le ja
Irukere ledu fi tumo won
Imo o to, imo o jo
Obalade n ko won bo wa
Yooyo,
Irukere ni fin kowon bo
Ewe olutumo mo pe o
Ti osan ba pon
Emi ni atumo
Ki o tumo iku, kio tumo arun, kio tumo ajogun welewele
Osunsun were were awo won ninu igbo
Adifafun gbirari eyi ti n se obinrin esu
Eniwipe eni tio barubo ti ko pe gbirara
Ki ebo re komo fin, kio mo da
Emi rubo L. O. L mope gbirare
Ki ebo re koda
Ki iku wa gbire ri
Karun o gbira ri
Woroko di e su wa gba
Eyin iyami osoronga wa gba
Tio basu waju, ki o fin
Tio ba bi seyin kio da
Tio ba duro loju kanna kio wode orun
Kofin leku dun
Kofin leja dun
Oro aifin ni ko sun han lodo oba orisa
Adifafun o n tuko
Omo obalufon
Ti n tepa osoro jako
Ogun oke ni fin sebo
Ebo re kofin
Won ni ori re ni o gbe ru
Ogbon oke ni fi n se etutu
Etutu re o da
Adota oke ni fi n sebo okookan koworun
Won ni oun buruku ni o sin leyin re
Ki oun buruku kio sin leyin re
Kio mo bebo lo
Kio fi otu se ijo
Kio fi owo alafia sayo
Ki eru buruku kio sokale leyin re
Kio mo ba ebo lo
Kio mo fi eti otun gbo asan
Kio mo fi tosi gbo igede
Ki oju o mo fomo lagbari
Kio mo fi enu siroso
Ki aru ko mo wo ni iku re
Kio mo lorunkun ejoo
Kio mo fese toogun mole
Alere abidi pete babalawo owo
Lo difafun owo
Omo asekun modi
Won ni kio mo sekun modi mo
Omo ni kio mo fi gbejo
Gbgbo nkan ti oba n fi owo re se ire ni kio ma je (ase)
Osebi lebi
Oseka leka
Ni gbe ebo fun ni
Niki duro gba
Emi kose ibi lebi
Emi kose ika leka
Mofi owo otun gbe fun
Mofi tosi gba
Ti ba goju opon
Kio fin
Tio ba gori owo kio da
Tio ba gun ori ile
Orun elebo ni lo
Abodi awo ile
Lo difafun ile
Nijo omode babu ile
Ojo na ni di
Ile afio seri ni oo
Ao fi run bo
Ti won ba ni won o ru
Kio pe won ru
Ti won ba ni won o tu
Kio pe won tu
Ti opon base
Ki iwo ile kio wa seri si.
Iye okanran osa
Ki gbe bo re kio sun na
Adimuye adimu ogbo
Adimuye adimu ato
Erin dio mu
Erin yaso
Efon diomu
Efon yajana
Agbanrere dio mu
Oyawo lori sarasara
Adifafun yere ara igi
Abufun tope
Yere ara igi ni won
Tope ki won danu
Agbakinmu ki ku
Adopemu kio ru
Aisa gorope
Kiku o pani
Ti iku ba n bo kio bomi
Bi arun ba n bo kio bomi
Bi ofo ba n bo kio bomi
Bi ajogun gbogbo ba n bo kio bomi
Nijo ire aje ba n bo kio simi sile
Nijo ire aya ba n bo kio simi sile
Nijo ire isegun ba n bo kio simi sile
Nijo ire gbogbo ba n bo kio simi sile
Alaja loko lami
Ki n mori mi lapo aye ja